Lati ro awọn agbẹ lagbara lati le ‘roko bọ́dún dé’, ile-ifowopamọ tilẹ
Naijiria (CBN) gbe eto ẹyawo kalẹ funn gbogbo agbẹ to wa lorilẹ-ede Naijiria
eyi ti gbogbo awọn agbẹ ti n jẹ mudun mudun ẹ afi awọn agbẹ to wa ni ipinlẹ ilu
Eko.
Ninu ipade awọn ẹgbẹ agbẹ ti ipinlẹ Eko eyi ti akọroyin wa Bajepade Abayomi
wa nibẹ ni a gbọ pe awọn agbẹ ipinlẹ Eko letọ si owo iranwọ to to biliọnu meji
naira. Alaga ẹgbẹ naa Ọtunba fẹmi Oke jẹ ka mọ pe ninu biliọnu meji naira yi,
biliọn kan naira ni ẹgbẹ naa le gba atipe ti wọn ba fẹ gba biliọnu naa wọn nilo
ohun ti wọn ma fi duro. Nigbati wọn ṣe iwadii, wọn ri pe ni awọn ipinlẹ bii
Ogun, Oṣun, Kwara ati Ọyọ ti wọn ti ri owo tiwọn gba ijọba ipinlẹ naa lo bawọn
gba owo naa. Wọn ka si ijọb pinlẹ Eko lati ri pe ẹgbẹ agbẹ pinlẹ Eko ri owo tiwọn
gba amọ nnkan ko ti ṣẹnure fun wọn.
Ninu ifọrọwerọ ti wọn ni pẹlu ijọba ipinlẹ Eko, ijọba sọ pe bi owo naa ṣe
ma di dida dapada gan lo jẹ awọn logun nitori awọn ko le rọ owo ti awọn o ya lo
san pada. Ohun ti ẹgbẹ naa pinu si ni pe awọn ma lo ẹgbẹ alajẹṣẹku to wa ninu ẹgbẹ
naa atipe bi ijọba ba funkun mọ ẹgbẹ, ẹgbẹ ma fi tipa tipa mu awọn olori alajẹṣẹku
naa eyit i owo naa asi di gbigba pada.
Igba-keji alaga to sọrọ rọ awọn ọmọ ẹgbẹ ki wọn maa dẹkun adura ki ijọba le
gba atipe ki ijọba naa ma wo awọn niran nitori ti owo naa o ba di gbigba yoo
kan wa ni bẹ ni. Atipe ti wọn ba le ri gba, awọn agbẹ ma le ri owo ṣagbẹ. Ipe
wa lọ si ọdọ ijọba pe ti wọn ba le ri owo naa gba, wọn le fi ọwọ sowọpọ pẹlu awọn
agbẹ to jẹ pe wọn ma ra awọn ere oko naa ti wọn si le fojuto bi owo naa ṣe n di
dida pada.